ECOWAS kéde Ààrẹ Tinubu gẹ́gẹ́ bí alága fún sáà kejì

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ni wọn tun ti yan gẹgẹ Alaga ajọ Ecowas fun saa mi lẹyin ọdun kan to bọ si ipo naa.

Ọjọ kẹsan an oṣu keje ọdun 2023 ni wọn kọkọ kede Aarẹ Tinubu gẹgẹ bii Alaga ECOWAS.

Aarẹ orilẹede Naijria, ẹni to bẹrẹ saa rẹ gẹgẹ bi Aarẹ ni oṣu karun un ọdun 2023, ni wọn fun ni anfani lati se saa keji gẹgẹ bii Alaga ECOWAS lasiko ipade awọn olori orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS.

Ipade yii waye ni ile Aarẹ Naijiria to wa ni olu ilu Abuja.

Aarẹ Tinubu ni Aarẹ Naijiria kẹjọ ti yoo jẹ olori ajọ ECOWAS, ti aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari wa lara awọn to ti lo saa meji lasiko ologun ati ijọba awarawa gẹgẹ bi alaga ECOWAS.

Ninu ọrọ itẹwọgba ipo naa, Aarẹ Tinubu ni oun yoo gbajumọ bi ijọba awarawa yoo gboro si ni ilẹ adulawọ.

“Mo ti gba lati tẹsiwaju ninu iṣẹ ribiribi ti mo n se fun ajọ yii nitori ero wa si ijọba awarawa papọ. Ma tẹsiwaju lati se ohun to tọ ni ibamu pẹlu ilana ajó ECOWAS. Ẹ se gan an.”

“Mo ti yan Aarẹ Senegal, Bassirou Diomaye Faye, pe ko jọ, ko ba wa fi ẹsẹ kan de orilẹede Burkina Faso, Mali ati Niger Republic pẹlu Aarẹ orilẹede Togo, Faure Gnassingbé lati ba awọn ọmọ iya wa sọrọ pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu mi ati ajọ ECOWAS.

Ohun to yẹ ko mọ nipa ECOWAS

Ajọ ECOWAS ni wọn da silẹ lọjọ kejidinlọgbọn ọdun 1975 nibi apero kan to waye niluu Eko lorilẹede lati ibasepọ awọn orilẹede adulawọ ni apa iwọ oorun lọ lia si wahala.

Orilẹede mẹdogun ni wọn buwọlu lati darapọ ajọ naa.

Awọn ni Benin, Burkina Faso, Cabo Verde or Cape Verde, Cote D'Ivoire, The Gambia, Ghana, Guinea, Guinea Bissau, Liberia, Mali, Niger, Nigeria, Senegal, Sierra Leone ati Togo

Lati igba ti wọn ti ECOWAS silẹ, Aarẹ orilẹede Naijiria to ti jẹ alage ree

  • Yakubu Gowon - 1975 - 1975
  • Olusegun Obasanjo - 1977- 1979
  • Muhammadu Buhari - 1985 - 1985
  • Ibrahim Babangida - 1985 si 1989
  • Sani Abacha - 1996 - 1998
  • Abdulsalami Abubakar 1998 - 1999
  • Umaru Musa Yar'Adua - 2008 - 2010
  • Goodluck Jonathan - 2010 2012
  • Muhammadu Buhari - 2018 - 2019
  • Bola Tinubi - 2023- di asiko yii