Ṣé ó tọ̀nà láti lo irin ìgbàlódé tí wọ́n fi ń ṣàtúntò eyín bí ohun èlò fáàrí?

Irin igbalode ti won fi n satunto eyin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ to ṣẹlẹ si arabinrin kan torukọ rẹ n jẹ Ezinne Ojo nigba ewe rẹ lo ṣokunfa bi eyin ọọkan rẹ ko ṣe to daada mọ.

Ọpọlọpọ ọdun ni arabinrin naa fi koju ipenija ọhun, nipa bi ko ti le e rẹrin nita gbangba, bẹẹ lo si mọ nipa irin igbalode ti wọn fi n ṣatunto eyin, ṣugbọn ti ko kọbi ara si i.

Lọdun 2022, awọn dokita onisegun oyinbo meji kan gba a niyanju lati samulo irin naa, toripe yoo ṣeranwọ fun un.

Ojo ṣalaye fun BBC, ohun to wa lọkan rẹ lasiko to gbọ nipa irin igbalode naa “Emi ko ranti igba akọkọ ti mo gbọ nipa irin ọhun, sugbọn wọn sọ pe, ọna abayọ si iṣoro eyin mi ni.”

“Awọn dokita ṣayẹwo fun mi, wọn ni mo le lo irin naa” gẹgẹ bi Ojo ti wi.

Ẹgbẹ awọn dokita onitọju eyin ni ilẹ Naijiria, fi lede wi pe, nnkan bii aadọrin awọn oniṣegun oyinbo, lo lee ba eeyan ṣe atunto eyin, ṣugbọn owo gọbọi ni wọn fi n ṣatunto eyin ti ijamba ọkọ ṣakoba fun latigba ewe ẹni.

Arabinrin Ojo sọ pe,“Mo ni irin igbalode naa, owo rẹ ko wọn pupọ, Ẹgbẹrun lọna Ọtalelẹẹdẹgbẹrin odin mẹwaa Naira, (#750,000) ni.

“Mo nilo lati yọ mẹrin kuro lara eyin mi, leyi to tubọ ṣalekun owo naa, Ẹgbẹrun lọna Ẹẹdẹgbẹwaa Naira (#900,000) lo jẹ lapapọ.”

Ojo mẹnuba eredi ti owo irin ọhun fi wọn, “Mo mọọmọ gba ile iwosan aladani lọ, ki wọn maa bami ṣatunto eyin mi.”

Ọpọ eeyan lo ti sọ irin igbalode to wa fun atunto eyin naa di ohun elo faari ni orilẹ ede Naijiria lode oni, bo ti lẹ jẹ wipe owo ti wọn fi n ṣe e ko fi bẹẹ yatọ.

Eredi igbesẹ naa ni ko sẹyin bi nnkan ti n ri lori awọn ikanni abanidọrẹ gbogbo.

Arabinrin Mary, oniṣowo kan to fi irin igbalode naa si eyin sọ fun BBC pe, ori ẹrọ amohunmaworan ni oun ti kọkọ mọ nipa irin naa.

“Lati igba ti mo tiwa lọmọde ni mo ti maa wo sinima awọn ọmọde tilẹ okeere, ibẹ ni mo ti gbọ ọ ri.”

Mary ṣalaye bi irinajo eyin rẹ ti bẹrẹ, o ni, bi oun ti n dagba ni oun ṣakiyesi pe eyin oun ko to daada bo ti yẹ, leyi to sokunfa igbesẹ lilo irin igbalode ọhun.

Bakan naa, lo mẹnuba iye owo to n na nigba yoowu to ba fẹ lọ ṣayẹwo eyin rẹ nile iwosan.

“Owo pupọ ni mo maa n san nile iwosan ki dokita lee kọkọ yẹ eyin mi wo, ki n to sanwo itọju eyin gangan, mo tun maa n san owo lọsẹ mẹfa-mẹfa fun atunyẹwọ atigbadegba,” Mary ṣalaye.

Mary tẹsiwaju pe, “Mo gbagbọ ninu iṣẹ ti irin naa nṣe, bẹẹ lo jẹ ọna abayọ gboogi ti eeyan lee fi koju iṣoro eyin ti ko to daada, emi ko feran ilana ṣiṣe isẹ abẹ eyin, toripe o lee yọ danu lairo tẹlẹ.”

Irin ti wo maa n gbe si eyin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kini ipenija tawọn to n lo irin igbalode naa si eyin maa n koju?

BBC ba awọn obinrin meji kan ti irin igbalode naa wa ni eyin wọn sọrọ, wọn ni kii ṣe gbogbo ounjẹ ni wọn lanfaani lati jẹ, bakan naa ni kini ọhun maa n fa inira fun wọn lọpọ igba.

Mary ṣalaye lẹkun rẹrẹ pe, “inira eyin ọhun le gidi, nigba miran, mi o ni lee ṣe nnkan kan, tabi jẹun paapa, nigba to ya inira naa mọ mi lara, toripe kii lọ bọrọ.”

Arabinrin Ojo naa tọka sii pe, ko gbọdo si ẹran lile tabi agbọn lara awọn ounjẹ mi, nitori ki asopọ irin ma baa daru.

“Ọpọ igba ni irin ọhun maa n gun mi lẹnu, yi yọ rẹ si maa n mu inira dani.

Ojo sọ pe, “ijamba ọkọ lo sọ oun di ẹni ti eyin ọọkan rẹ daru latigba ewe, o ri bẹẹ ni ipele ikẹekọ alakọbẹrẹ, girama ati unifasiti mi, ki n to gbe igbesẹ atunto rẹ lẹyin o rẹyin.”

Ṣe iyatọ wa laarin irin atunto eyin ati eyi ti wọn fi n sẹ faari?

Eyin ti ko to dada

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Keye to n ṣetọju eyin nile iwosan Khings ṣalaye wi pe awọn eeyan maa n fi irin igbalode to wa fun atunto naa ṣe faari.

Dokita ọhun sọ pe, “Awa la maa n ṣo pato irufẹ irin igbalode eyin ti awọn eeyan ba nilo fun wọn, boya fun faari tabi fun atunto eyin ti ko to daada.”

O ṣalaye wipe, awọn ilana kọọkan wa ti wọn saba maa n tọ ki wọn to sọ pato irufẹ irin igbalode eyin fun ẹni to fẹ lo.

Dokita Keye sọ pe oriṣiṣi meji ni irin igbalode naa pin si, alawo ati onirin, ti lilo rẹ si da lori irufẹ ipenija eyin tabi erigi eeyan. Iru ẹni bẹẹ si gbọdọ maa wa fun ayẹwo lemọ lemọ ki eyin ọhun to lee pada sipo.

Dokita Keye tọka sii pe, “A kọkọ maa yẹ ibaṣepọ to wa laarin eyin, erigi ati agbọn isalẹ tabi oke wo boya iṣẹ wọn pe, ki a to mọ boya ẹni naa yoo nilo lati ṣatunto eyin tabi bẹẹ kọ.”

Bakan na ni Dokita Keye sọ pe, Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin si milliọnu kan Naira, ni owo ti eeyan nilo fun gbigba irin igbalode atunto eyin naa, ni gbogbo ile iwosan ijọba ati aladani to wa kaakiri orilẹ ede Naijiria.