Bussiness tips: Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀

Apẹrẹ eso

Oríṣun àwòrán, other

Iṣẹ agbẹ da le gbingbin awọn ohun ọgbin ati sinsin awọn ohun ọsin fun igbayegbadun ọmọ eniyan. Ọpọ lo si maa fẹ ṣe ọgbin ṣugbọn to jẹ wi pe aisi aye to to lati ṣe iṣẹ ọgbin n di wọn lọwọ.

Eniyan nilo ounjẹ lati lee dagba ki o si wa laye ati lati ni okun ati agbara lara ṣe iṣẹ oojọ rẹ gbogbo.

Ẹ jẹ ki a wo diẹ lara awọn iṣẹ okoowo ti o lee ṣe ni gbagede ile rẹ.

Ata:

Ata

Oríṣun àwòrán, other

Eyi le jẹ ata pupa tabi ata dudu tabi ata bẹẹbẹ.

Ata rọrun lati gbin, ko si fẹrẹ si oriṣi ilẹ kan ti ko tii le gberu. Ko si si ọja kan ti a kii tii ri awọn to n ta ata. Gbogbo eeyan lo n lo ata nitori awọn agba a maa da aṣamọ kan pe, 'ẹmi ti ko jẹ ata, ẹmi yẹpẹrẹ ni.'

Àkọlé fídíò, Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

Ọsin Ehoro:

Ehoro

Oríṣun àwòrán, other

ehoro jẹ ẹran kan ti awọn eeyan maa n fẹran lati jẹ. Wọn kii pa ariwo, bẹẹ ni wọn kii da wahala tabi ẹgbin silẹ layika bi awọn ẹran ọsin miran bii aja.

Bi eniyan ba ti lee kan ago fun un, o lee bẹrẹ pẹlu ẹbi kan tabi meji ki o si fi wọn silẹ lati maa gun. Owo Ehoro to ba pe oṣu mẹrin a maa to ẹgbẹrun marun un Naira nigba miran.

Olu:

Olu

Oríṣun àwòrán, other

Ọpọ eeyan lo maa n fẹran olu jijẹ, a lee fi se ọbẹ, tabi ohun ajẹgbadun bii Pizza. Inu awọn igi to wo to si ti n jẹra atawọn ohun ira miran ni a ti lee ri olu.

Lati gbin in, o le raa ni ọja, wu u ni oko tabi lọdọ awọn to ba n ṣe ọgbin rẹ. Inu ike to ni awọn ohun to ti doku ni ki o koo si. Wa lu iho si ara ike naa lati fi aye silẹ fun atẹgun lati maa wọle.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

Tomato:

ohun ọgbin kan to tun rọrun lati gbin ni Tomato jẹ. Ẹ le ko eso rẹ sinu ike tabi agolo kan ti ẹ ti bu ilẹ si ninu.

Ohun ti eeyan nilo naa ni ilẹ, oorun ati omi. Ọja Tomato kii kuta lọpọ igba nitori awọn ti yoo raa wa lọpọ yanturu.

Tomato

Oríṣun àwòrán, Tomatoes

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

Ewebẹ:

Ọpọlọpọ awọn eeyan lo fẹran awọn ewebẹ tutu. O maa n mu adidun ba ounjẹ. A le gbin ewebẹ si ayika ati gbagede ile wa. O si le pa ọpọlọpọ owo lati ara gbingbin ewebẹ. Awọn ewebẹ bii ila, ẹfọ loriṣiriṣi ati bẹẹbẹẹlọ a maa gberu daadaa ni ayika gbagede ile.

Ewebẹ

Oríṣun àwòrán, other

Bi o ba dẹ jẹ pe wọn ti fi sanmọnti kọnkere ilẹ ile rẹ, o lee lo garawa tabi aloku taya ọkọ. da ilẹ sinu wọn ki o si gbin eso nnkan to fẹ gbin.

Iwọ naa lee maa fi eyi pa owo si apo rẹ.

Àkọlé fídíò, Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ f���wọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....