Àdó olóró Russia balẹ̀ sílé ìwòsàn ọmọdé ní Ukraine, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù

Ukraine

Oríṣun àwòrán, getty images

Ko din ni eeyan mọkanlelọgbọn to ti jade laye ni Ukraine bayii lẹyin ado oloro Russia to n dun leralera kaakiri orilẹede naa.

O kere tan, eeyan mẹtadinlogun lo ku ni Kyiv ninu ikọlu to waye lọsan an gangan, to fi mọ awọn meji to jade laye nileewosn awọn ọmọde kan, Ohmatdyt Children's Hospital.

Oloori ileeṣẹ ọmọ ogun niluu Kryvyi Rih sọ pe eeyan mẹwaa lo ku nibẹ, ti awọn mẹta mii tun ku niluu Pokrovsk ati ẹnikan niluu Dnipro.

Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky, to ṣabẹwo si Poland lori ọrọ eto abo ti sọ pe oun yoo gbẹsan ikọlu naa.

Zelensky ni “oniruru ilu bii Kyiv, Dnipro, Kryvyi Rih, Sloviansk, Kramatorsk.

“Oniruru ado oloro bii ogoji lo ti balẹ sawọn agbegbe bii ile gbigbe, awọn ohun amayedẹrun ati ile iwosan awọn ọmọde ni ado oloro ti bajẹ.”

Ọkan lara awọn dokita ile iwosan awọn ọmọde ọhun, Lesia Lysytsia, sọ fun BBC pe niṣe lo ad bii fiimu loju oun lasiko ti ado oloro naa balẹ sile iwosan ọhun.

O ni “Apakan ile iwosan naa dawo nigba ti ina n jo lapa keji rẹ, nnkan bii ida 60% si 70% ile iwosan ọhun lo ti dawo.”

Aworan lati ile iwosan naa ṣafihan awọn ọmọde ti wọn joko sita pẹlu ohun ti wọn fi n fa omi si wọn lara niwaju ile iwosan naa.

Dokita Lysytsia sọ pe ile iwosan nla ni ile iwosan naa jẹ, o si jẹ ibi ti wọn ti n ṣetọju oniruru aisan bii arun jẹjẹrẹ, wọn si tun maa maa n paarọ ẹya ara nibẹ pẹlu.