Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Naijiria fòǹtẹ̀ lu ìbálòpọ̀ akọsakọ nípasẹ̀ àdéhùn Samoa tó buwọ́lù?

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Iwadii ileeṣẹ iroyin BBC ti fi han pe adehun Samoa ti Naijiria ṣẹṣẹ tọwọbọ ko tumọ si pe o ti fontẹ lu ibalopọ akọsakọ ati abosabo.

Ninu iwe adehun naa to ni oju ewe 172, eyii ti BBC foju ri loju po ajọ European Commission, ko si abala kankan ninu rẹ sọrọ nipa ibalopọ akọsakọ ati abosabo.

Amọ ṣa, adehun ọhun mẹnuba igbeṣe lati dẹwọ idunkomọni latari ẹsin ti eeyan n sin, tabi ẹni to ba yan lati ni ibalopọ pẹlu.

Yatọ si ilẹ Afirika to tọwọ bọwọ adehun naa, awọn ilẹ mii bii Caribbean ati Pacific naa gbọdọ ṣe ohun to wa ninu adehun ọhun lẹyin ti wọn tọwọ bọ ọ.

Abala kọkanla ninu adehun naa sọ pe awọn orilẹede to lọwọ si yoo dẹwọ “idunkokomọni latari ibi ti eeyan ti wa, ẹya, awọ, ede, ẹsin, oṣelu... ọjọ ori tabi ọrọ ibalopọ.”

Lati igba ti iroyin ti jade nipa adehun naa lawọn iroyin kan ti n lọ kaakiri pe Naijiria yoo janfani $150b lori adehun naa.

Amọ ṣa, ileeṣẹ to n ri si etio iṣuna ni Naijiria ti sọ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Bolaji Adebiyi, o ni ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Bolaji ni “ko si adehun $150b kankan, iroyin ẹlẹjẹ lasan ti awọn ileeṣẹ iroyin n gbe kiri ni.

“Adehun Samoa ni ijọba buwọlu, ileeṣẹ wa si ti fi ọrọ lede nipa ohun ti adeun naa jẹ.”

Ninu iwadii BBC, a ri pe lootọ ni ko si adehun $150 kankan ninu adehun Samoa ọhun ti ijọba Naijiria buwọlu.

Kí lò wà nínú ìwé àdéhùn Samoa tí Nàíjíríà tọwọ́ bọ̀, èyí tó di awuyewuye?

Aare

Oríṣun àwòrán, @OfficialBAT

Iwe adehun Samoa jẹ agbekalẹ ilana ofin fun ajọsepọ laarin ẹgbẹ awọn orilẹede nilẹ Afirika, Caribbean ati Pacific states (OACPS) ti ibujoko rẹ wa ni Brussels ni Belgium ati ajọ isọkan ilẹ Yuroopu.

Afojusun iwe adehun Samoa ni lati mu agbega ba eto idagbasoke to fẹsẹmulẹ, gbigbogun ti ayipada oju ọjọ ati awọn ipa to n ni lara ẹda.

Bakan naa ni iwe adehun ọhun wa lati se agbekalẹ anfaani ọna idokowo pọ, ki ajọsepọ to gunmọ si tun wa laarin awọn orilẹede to wa ninu ajọ ni awujọ agbaye.

Lọjọ kẹẹdogun, oṣu kọkanla, ọdun 2023, ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu (EU) ati awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ parapọ lati tọwọ bọ iwe adehun ajọṣepọ tuntun yii, eyi ti wọn pe ni iwe adehun Samoa (Samoa Agreement Deal).

Latigba ti iroyin ọhun ti jade sita wi pe ijọba Naijiria ti tọwọ bọ iwe adehun ti Samoa yii, lo ti di ohun ti awọn eeyan n gbe kaakiri bayii, ti iroyin ọhun si ti wa di ariyanjiyan nipa ohun ti iwe adehun naa jẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn tọwọ bọwe adehun yii ni wọn jẹ ti Organisation of African, Caribbean and Pacific States (OACPS).

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn jẹ mẹtadinlọgbọn ninu ajọ iṣokan ilẹ Yuroopu ni wọn tọwọ bọwe adehun yii, ti awọn ilẹ Afrika mọkandinlọgọrin, Caribbean ati Pacific si wa ninu wọn ni wọn jọ panupọ lati tọwọ bọwe adehun yii.

Iye awọn to wa ninu orileede to tọwọ bọwe adehun yii le ni biliọnu kan aabọ.

Ki lo wa ninu iwe adehun Samoa yii gangan eyi to n fa awuyewuye?

Gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye ti wi, iwe adehun Samoa yii da lori koko pataki mẹta to jẹ wọn logun.

Bakan naa, ajọ OACPS ṣalaye pe iwe adehun naa jẹ eyi to n ṣatilẹyin fun ẹtọ ọmọniyan, eto oṣelu awa-arawa ati iṣejọba to dara, eyi to tun faaye gba ori ko j’ori ọkunrin ati obinrin ninu eto oṣelu ati iṣejọba, to fi mọ titẹle ilana ofin.

Wọn tun ni iwe adehun Samoa yii ni lati mu ayika to dara wa, lati ṣe eto ọrọ aje lanfaani lati duro ṣinṣin.

Lara rẹ si ni ‘ẹtọ ọmọniyan, eto oṣelu awa-arawa ati iṣẹjọba to dara; alaafia ati aabo; igbayegbadun awọn eeyan; bi eto ọrọ aje yoo ṣe lagbara sii ati idagbasoke rẹ; ayika ati agbegbe ti yoo ṣe ayipada oju ọjọ lanfaani rere; to fi mọ kikolọ si ibomiran lọna irọrun’

Iwe adehun yii ni wọn fẹnu ko le lori nibi ipade igbimọ awọn minisita ti ACP-EU, ẹlẹẹkẹrindinlaadọta iru rẹ, eyi to waye ṣaaju ki wọn to tọwọ bọ iwe adehun Samoa ọhun.

Iwe adehun Samoa yii ni wọn n foju sọna fun lati mu ohun gbogbo rọrun fun idaṣẹsilẹ, ibadọrọ nipa idowopọ, ṣiṣagbelarugẹ idagbasoke ati alaafia fun gbogbo awọn to pawọpọ lori rẹ.

Akọwe apapọ fun Organisation of African, Caribbean and Pacific States, Georges Rebelo Pinto Chikoti, sọ pe ohun to wa ninu ajọṣepọ iwe adehun 'OACPS-EU ni lati wa idagbasoke otitọ ati ajọṣepọ to dan mọnran nipa ifọwọsowọpọ rere.’

Ki ni awọn ọmọ Naijiria n sọ nipa bi Naijiria se fọwọ si iwe adehun naa?

Awọn ẹgbẹ Musulumi kan ti wọn pe ni Hijrah Islamic Organisation ati Ansarul-Islam Society of Nigeria bu ẹnu atẹ lu wi pe awọn tako bi ijọba Naijiria ṣe tọwọ bọwe adehun lati faaye gba igbeyawo laarin abo ati abo, pẹlu akọ ati akọ lati le fi ya owo to to aadọfa biliọnu owo dọla.

Awọn meji naa sọ pe iwa ọhun tako ẹsin Islam, bẹẹ ni wọn tun sọ pe iwa to tabuku ba idagbasoke ati ilọsiwaju orileede ni.

Wọn ni Islam tako igbeyawo laarin akọ ati akọ, pẹlu abo ati abo.

Awọn adari ẹgbẹ mejeeji yii wa rọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati ma ṣe gba eyi wọle, ati pe iwa to n pe fun iyọnipo ni, ati pe ki wọn tete gbe igbesẹ to yẹ lee lori.

“Ki ile igbimọ aṣofin ṣagbeyẹwo iwa yii gẹgẹ bi iwa to n pe fun iyọnipo, ki wọn si gbe igbesẹ to yẹ lee lori.

Ki awọn olori ẹlẹsin tete sọrọ jade, ki wọn si ke pe Ọlọrun lati dide si ọrọ orileede yii. O to gẹẹ.”

Ninu ọrọ agbẹnusọ ajọ Ansarul-Islam Society of Nigeria, ẹka tiluu Ilọrin, Imam Abubakar Aliy–Kamal sọ pe “Ẹsin Islam tako igbeyawo laarin akọ ati akọ pẹlu abo ati abo, ati pe orileede korileede to ba n huwa yii yoo ri ibinu Allah, ibinu Aalah yoo si wa lori gbogbo wọn.

“Dipo yiya owo yii, mo fẹẹ gba Aarẹ Bola Tinubu lamọran lati gbajumọ ọrọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin, to fi mọ awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n mu ilọsiwaju orileede fun anfaani awọn ọmọ Naijiria.”

Bakan naa, akọwe ipolongo ẹgbẹ Afẹnifẹre, Kọmureedi Jare Ajayi ninu ọrọ rẹ sọ pe bi gbogbo ọmọ Naijiria ṣe dide lati tako bi ijọba ṣe tọwọ bọ iwe adehun ti fi han daju pe wọn ko faaye iwa buruku to tako igbe aye ati ilana ọmọniyan.

Ajayi ran awọn eeyan leti bi Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Jonathan ṣe buwọ lu ofin to tako igbeyawo laarin akọ ati akọ, to si ni iwe ọdaran ni yoo jẹ bi ọwọ ba tẹ ẹnikẹni, iyẹn lọdun 2014.

Ijọba fesi lori bawọn ọmọ Naijiria kan se n fapa janu nipa iwe adehun Samoa

Minisita feto iroyin, Muhammed Idris ti fesi lori bi awọn ọmọ Naijiria kan se n fapa janu lori iwe adehun Samoa ti ijọba apapọ bu ọwọ lu.

O ni ijọba Naijiria tọwọ bọwe adehun Samoa lootọ amọ ọna lati si awọn araalu lọna ni awuyewuye to n lọ pe iwe adehun ọhun yoo faaye gba igbeyawo laarin ọkunrin si ọkunrin ati obinrin si obinrin nitori pe ko si otitọ ninu ẹ.

Bakan naa lo ni iwe adehun ti ijọba tọwọ bọ wa fun idagbasoke ati ilọsiwaju Naijiria nikan ni.

"Ijọba Bola Ahmed Tinubu ko ni fọwọsi igbesẹ tabi adehun to le se ijamba fun ifẹ awọn eeyan orilẹede yii.

“Erongba naa ni lati ṣagbelarugẹ fun idagbasoke, gbigbogun ti ayipada oju ọjọ, lati gbaruku ti awọn anfaani idaṣẹsilẹ ati okoowo ṣiṣe, ati ajọṣepọ laari awọn ọmọ ẹgbẹ OACPS kaakiri agbaye.”

Muhammad Idris, sọ pe lara ohun to wa ninu iwe adehun naa ni igbelarugẹ ati idagbasoke akanṣe iṣẹ ode ti agbegbe, ati pe awọn orileede ilẹ Afrika, to fi mọ Caribbean, ati Pacific ti a mọ si OACPS ni wọn ṣagbekalẹ iwe adehun naa.

Bẹẹ lo tun sọ pe iwe adehun kan naa tun wa ti wọn pe ni OACPS, eyi to ti jẹ itẹwọgba lati ọdọ ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu nibi ipade apapọ agbaye wọn, ẹlẹẹkẹtalelaadọrin iru ẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni "ofin mẹtalelọgọrun lo wa to ti de ipele titọwọ bọ, ṣugbọn eyi to ṣe koko ti a ni lati jẹ ko ye wa nibẹ ni pe awọn iwe adehun yii ni wọn gbe kalẹ ni ibamu pẹlu ilana ofin, eyi ti yoo faaye gba ifọwọsowọpọ laarin OACPS ati EU fun idagbasoke awọn agbegbe, ati lati pese owo fun idaṣẹsilẹ, lati dena ayipada oju ọjọ, kii ṣe bi awọn eeyan 'se n gbe kaakiri."

O fi kun ọrọ rẹ pe "Ojuṣe wa ni lati fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe Naijiria, ijọba Bọla Tinubu ko nii tọwọ bọwe adehun ti yoo tako ifẹ araalu."

Tun wẹ, Agbẹnusọ fun aarẹ Tinubu, Bayo Onanuga naa ti salaye loju opo X rẹ pe irọ lasan, ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ni awuyewuye to n lọ kiri pe iwe adehun Samoa yoo fi aaye gba igbeyawo laarin ọkunrin si ọkunrin ati obinrin si obinrin.

Atẹjade ti Bayo Onanuga fisita

Oríṣun àwòrán, @aonanuga1956