Wo agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà méjì míì tó ti mi àwọn nínú eré bọ́ọ̀lù àṣekágbá Europa League yàtọ̀ sí Lookman

Aworan Ademola Lookman

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹlẹsẹ ayo fun ikọ Super Eagles ati Atalanta lorilẹede Italy, Ademola Lookman lo ti fi itan balẹ gẹgẹ agbabọọlu orilẹede Naijiria kẹta tí yoo mi awọn ninu ere bọọlu aṣekagba idije Europa League.

Ikọ Alatanta koju ikọ Bayer Leverkusen ninu ipele asekagba idije naa, ninu eyi ti Alatanta ti pokọ iya fun wọn lẹyin ti Lookman gba goolu mẹta ọtọtọ sawọn.

Ifẹsẹwonsẹ ọhun lo waye ni paapa isere Aviva niluu Dublin lorilẹede Ireland.

Saaju Lookman, agbabọọlu ikọ Super Eagles meji ti mi awọn fun ẹgbẹ agbabọọlu wọn ninu idije Europa.

Agbabọọlu akọkọ ni Alex Iwobi nigba to wa pẹlu ikọ Arsenal lọdun 2019 nigba ti Ikọ Arsenal koju Chelsea.

Aworan Alex Iwobi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ami ayo mẹrin si ẹyọ kan lo pari ìfẹsẹwọnsẹ naa, to si jẹ pe Iwobi lo mi ami fun ikọ Arsenal sugbọn sibẹsibẹ wọn fìdí rẹmi niwaju Chelsea.

Agbabọọlu kejì Joe Aribo nigba to gba bọọlu fun ikọ Ranger lọdun 2022.

Ikọ Rangers ati Frankfurt lo gba ipele asekagba naa ti ìfẹsẹwọnsẹ naa si pari pẹlu ọmi.

Aribo lo mi awọn fun ikọ Rangers sugbọn oun ati ẹgbẹ agbabọọlu rẹ pada fidi rẹ mi.

Aworan Joe Aribo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ta ni Ademola Lookman taye n sọ nipa rẹ bayii gan an?

Aworan Ademola Lookman

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun 2015 ni Ademola Lookman bẹrẹ irinajo bọọlu gbigba pẹlu ikọ Charlton Athletic.

Odun 2017 lo darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Everton.

O kopa fun igba akọkọ ninu idije Europa fun ikọ Everton nigba ti wọn pade MFK Ruzomberok.

O tẹsiwaju lọ darapọ mọ ikọ RB Leipzig ni Ibẹrẹ ọdun 2018.

Lookman tọwọbọ iwe adehun ọlọdun marun un pẹlu ikọ RB Leipzig ko to di pe wọn fi sọwọ sì ikọ Fulham lọdun 2020.

Lọdun 2021, o gbera lọ darapọ mọ ikọ Leicester City ko to wa morile Ikọ Alalanta FC lọdun 2022.

Irinajo Lookman si ikọ Super Eagles Naijiria

Aworan Ademola Lookman

Oríṣun àwòrán, Others

Orilẹede Gẹẹsi ni wọn bi Lookman man, ti awọn Obi rẹ mejeeji si jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.

O bẹrẹ si ni gba bọọlu fun ikọ England, to si kopa ninu idije U19 fun England.

Lọdun 2020 ni Lookman yii ero rẹ pada to si pinnu lati gba bọọlu fun ikọ Super Eagles orilẹede Naijiria.

Igba mẹta ọtọọtọ ni o kọ lati gba bọọlu fun ikọ Super Eagles ko to yi ero rẹ pada.

Ademola Lookman

Oríṣun àwòrán, NG Super Eagles