Yóò lé ní ọgọ́rin míliọ̀nú ọmọ Nàìjíríà tí yóò máa kojú ebi ni ọdún 2030- MDD

Aworan ounjẹ ni ọja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ agbaye UN ti sekilọ pe eeyan lo ni ọgọrin milọnu to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ni o ṣeeṣe ki wọn koju ebi ni ọdun 2030.

Ẹka to n ri ounjẹ ati ọgbin ni ajọ agbaye UN lo gbe iwadii yii kalẹ lati se afihan bi nnkan yoo se ri ni lorilẹede Naijiria ni ọjọ ọla.

Bakan ni MDD tun kesi orilẹede Naijiria lati wa ojutu si iṣoro oju ọjọ, iṣoro kokoro ati awọn nnkan mii to n dunkoko mọ eto ọgbin lorilẹede Naijiria.

“Ijọba orilẹede Naijiria pélu ajọsepọ awọn ti ọrọ kan, ti gbe iwadii dide lori eto ọgbin ati ounjẹ. Abo iwadii naa lo mu ibẹru dani nitori o le ni eeyan milọnu mejileọgọrin ti yoo koju ebi to ba di ọdun 2030,” Taofiq Braimoh ṣalaye fun awọn akọroyin niluu Abuja.

O tẹsiwaju pe iṣoro ounjẹ ti a ni lorilẹede Naijiria ni o tan mọ kudiẹkudiẹ oju ọjọ ati bi awọn kokoro se n fa ọpọ ijamba to n waye ni ẹka ọgbin lorilẹede Naijiria.

Ọrọ ti ajọ Agbeye UN gbe jade yii lo n waye ni asiko ti ọwọngogo ounjẹ gbode lorilẹede Naijiria, ti ọpọ ile to si ni anfani lati ri ounjẹ si ile bi ti tẹlẹ mọ.

Bakan naa ninu iwadii kan to jade sita, UN ni ida ogoji tun ti gun ori owo ounjẹ lorilẹede Naijiria, ti eyi si jẹ ohun ti ko sẹlẹ ri.

Lọdun to kọja, Aarẹ Bola Tinubu kede ilu o fararọ lori ọrọ naa, ninu igbiyanjulati ko ounjẹ sita fun araalu.

Laipẹ ni ijọba tun kede awọn igbesẹ kan lati irọrun deba nnkan ti awọn araalu n la kọja lasiko yii.

Ókan lara igbesẹ ijọba ni pe ijọba yoo ko ounjẹ to jẹ tọnu mejilogoji sita fun awọn araalu, ti ẹka eto ọgbin yoo se amoju to rẹ.