Ìgbéyàwó fún àwọn ọmọ òrukàn 105 yóò wáyé ní Zamfara

Aworan awọn ọmọge

Oríṣun àwòrán, KOLA SULAIMON/AFP

Oni ni igbeyawo awọn ọmọ alalobi marun le ni ọgọrun un ti wọn padanu obi wọn sọwọ ikọlu awọn agbebọn ni ilu Bungudu nipinlẹ Zamfara.

Aṣofin Abdulmalik Zubaim Bungudu to se agbatẹru igbeyawo naa sọ fun BBC pe awọn gbe igbimọ kalẹ lati se ohun to tọ nipa awọn ti yoo jẹ anfani naa.

“A ti ṣawari awọn ọdọmọbinrin marun le ni ọgọrun un, ti wọn ko ki n se opo, sugbọn ti wọn jẹ ọmọge, ti wọn padanu awọn obi sọwọ ikọlu awọn agbebọn.

“A yoo pase iranlọwọ fun wọn nipa ohun ti wọn yoo fi bẹrẹ igbesi aye lọkọlaya ati pe a yoo fun wọn ni owo lati bẹrẹ idokowo.”

O fikun pe ki wọn to gbe lati se igbeyawo fun awọn ọmọge naa, awọn ti gbe awọn igbesẹ to yẹ lati mọ boya awọn ọdọ ni yoo jẹ anfani yii.

“O gbọdọ jẹ ọmọge to padanu awọn obi rẹ, ti ko mọ ọkunrin ri ati ti ko ni ọkọ ri.

”A yoo fun awọn owo lati bẹrẹ idokowo ati awọn ti wọn yoo nilo”

Irufẹ igbeyawo bayii ki nse nnkan ajoji ni apa ariwa orilẹede Naijiria, ti wọn si ti n se tipẹ lati se iranlọwọ fun ọmọge to ti balaga lati se igbeyawo sugbọn ti wọn ti padanu awọn obi wọn.

Ayẹye ma n waye nipinlẹ Kano, Niger ati Kebbi nibi ti wọn ti ma so ogunlọgọ obinrin ati ọkunrin papọ gẹgẹ bi tọkọtaya.

Bẹẹ ba gbagbe, ede ayede waye laarin minista fun ọrọ obinrin lorilẹede Naijiria, Uju kennedy ati Olori ile aṣofin ipinlẹ Niger, Mohammed Abdulmalik Sarkin-Daji lori ero rẹ lati se igbeyawo fun ọmọge to le ni ọgọrun un nipinlẹ Niger.

Ọrọ yii dọrọ ile ẹjọ sugbọn igbayawo naa pada waye.