Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìlú ńlá kan wà lórí òkè Idanre?

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìlú ńlá kan wà lórí òkè Idanre?
Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìlú ńlá kan wà lórí òkè Idanre?

Ilu Idanre jẹ ọkan lara awọn ilu ilẹ Yoruba to ti wa fun igba pipẹ, to si da yatọ laarin awọn ilu mii.

Yatọ si ede wọn, ọpọ okowo lo wa w ni ilu Idanre. Iyan ati Egusi ni ounjẹ Idanrẹ, to si jẹ ilu to rẹwa pupọ.

A fi ẹsẹ kan de Oke Idanre, nibẹ ni a ti mọ pe ilu mii si n wa lori oke.

O ya yin lẹnu abi? Bẹẹ ni, ilu kan n bẹ lori Oke Idanre, to si ni ile ẹkọ ati Aafin Oba niluu naa.

Gbenga Oyinbo, to jẹ olupitan ṣalaye fun BBC Yoruba pe ilu Idanre jẹ ọkan lara ilu to ti pẹ nilẹ Yoruba, tawọn oyinbo n pe ni iluu atijọ,

Aworan akasọ 682 lọ sori oke Idanre

O ni ọdun 1928 ni awọn eeyan sọkalẹ lati oke naa.

“Igba kan n bẹ lori oke ni igba yẹn, awọn ẹlẹsin Kristẹni; wọn wa ki wọn, ni igba tawọn wọnyii de, wọn kọ awọn eeyan Idanre bi wọn ṣe n kọ ati maa ka, wọn tun n waasu iyin rere

“Igba tawọn kan yipada, ti wọn di Kristẹni, o ni aawọ to fẹ wa laaarin awọn Oniṣẹmbaye ati awọn Kristẹni, ohun lo fa a ti awọn to sẹsẹ gba iwaasu iyin-rere fi sọkalẹ ni odun 1928.”

Lati gun oke Idanre, akasọ 682 ni a gun ki a to de ilu naa.

A fi oju ganni Ile ẹkọ akọkọ niluu Idanre, Ile ẹjọ, Ọja ati Aafin Oba ilu Idanre.

Ni ori oke, ibi tawọn Idanre gbe laye igba yẹn, tẹ ẹ ba wo ayika, tẹ ẹ ba wo apa osi, tẹ ẹ wo apa ọtun, ẹ ẹ ri pe ori ilẹẹlẹ ni

Oyinbo ni “to ba jẹ eeyan ti o ti de isalẹ ri, wọn ko le ro lọkan wọn wi pe; ori-oke ni wọn wa, ẹ ri bi ilẹẹlẹ ṣe ri nisinyi, ẹ ri pe a ti wa lori ilẹẹlẹ, ibi ti ẹru Ọlọrun ti ba mi niyẹn.”

BBC kọ wọrin pẹlu Gbenga Oyinbo lati fi oju ganni awọn nnkan ara to wa ninu ilu to wa lori Oke Idanre.

Ẹ wo fọnran yii lati mọ nipa ilu Idanre ati ilu to wa lori oke Idanre.