Wo àwọn ìwà àìmọ̀kan tí ò ń hù lójúmọ́, tí o fi ń kópa nínú ìlòkulò òògùn láì mọ̀

Aworan obinrin to n loogun

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe aṣilo oogun jẹ arun to n maa n ṣakoba fun ọpọlọ ati iwa eeyan, o ṣi n maa jẹ ko nira fun iru ẹni bẹẹ lati maa tẹle awon alakalẹ dokita lori oogun lilo.

Ọti lile, igbo ati eroja nicotine to wa ninu siga wa naa wa lara awọn oogun t'awọn eeyan maa ṣe asilo rẹ ti a n sọ yii.

Awọn dokita onimọ iṣegun sọ pe aṣilo oogun maa n bẹrẹ nigba t'awọn eeyan ba lo oogun ti wọn ti ko fun ẹlomiran.

Nigba to ba ya, iru ẹni bẹẹ yoo bẹrẹ si ni lo oriṣii oogun ki oju rẹ le baa le.

Ewu to wa ninu asilo oogun pọ, o ṣi da lori iru oogun ti eeyan ṣilo.

Eyi si lo mu ki BBC Yorùbá bá Dókítà Adekunbi Adedayo sọrọ lori ọna ti awọn eeyan n gba se asilo oogun.

Awọn ami to n ṣafihan aṣilo oogun

  • Lara awọn ami asilo oogun ni ki eeyan fẹ maa loogun ni gbogbo igba.
  • Ki eeyan ma le ro nipa nnkan mii yatọ si oogun lilo.
  • Nigba ti o ba n fẹ lati maa lo iru oogun kan naa ni gbogbo igba.
  • Rira oogun ti o mọ pe o ko ni owo lati ra.
  • Ai le ṣe ojuṣe mọ lẹnu iṣẹ tori aṣilo oogun.
  • Nigba ti o ba tẹsiwaju lati maa loogun, bo tilẹ jẹ o n ṣakoba fun ara rẹ
  • Jija ole lati le ri pe o ra oogun fun lilo.
  • Wiwa ọkọ tabi ṣiṣe ohun lile mii, nigba ti o mọ pe oogun oloro ti o lo ti n yọ ọ lẹnu.
  • Nigba ti o ba n ni ijakulẹ ninu igbiyanju lati dẹkun lilo oogun oloro.
  • Ṣisa ibi iṣẹ tabi ile ẹkọ.
  • Ai ni okun, oju pipọn ati ki eeyan ru.
  • Ayipada ihuwasi eeyan.

Wo ọna tawọn eeyan ṣe n ṣi oogun lo lai mọ

  • Nigba ti oogun ti o lo ba kere tabi ju iwọn t'awọn dokita ni ki o lo lọ.
  • Nigba ti o ba lo oogun ti wọn ni ki o lo lọsan an lalẹ.
  • Nigba ti o ba tiẹ gbagbe lati loogun rara nigba t'awọn dokita ni ki o lo o.
  • Nigba ti o ba ṣadeedee da oogun lilo duro, bo tilẹ jẹ pe ko tii to asiko lati ṣe bẹẹ.
  • Lilo oogun fun idi miran yatọ si ohun táwọn dokita ni ki o lo o fun.
  • Lilo oogun to wu ọ lai ṣe wi pe dokita lo sọ pe ki o lo o

Igba ti o le ri dokita ree lori aṣilo oogun

Dokita onimọ iṣegun Adedayo sọ pe ti o ba ti ri i pe aṣilo oogun ti n fa oriṣiiriṣii iṣoro fun ọ, tete lọ ri dokita.

Bi eeyan ba ti yara lọ ri dokita ni o maa sọ bi ati gbadun rẹ yoo ṣe ya si.

Igba ti o nilo lati ri dokita ni kiakia ni igba ti o ba lo oogun ju iwọn tawon dokita sọ pe ki o lo lọ.

O ni lati ri dokita ni kiakia nigba ti o ba le mi daadaa mọ latari oogun ti o lo.

O ni lati ri dokita nigba ti o ba n ni giri latari aṣilo oogun.

Nigba ti aya ba n dun ọ lẹyin ti o lo oogun tan, tete lọ ri dokita.

O ni lati tete lọ ri dokita nigba ti ara rẹ ba n ṣe bakan lẹyin o loogun tan.

Wo ọna tawọn eeyan ṣe n ṣi oogun lo lai mọ

Aṣilo oogun tun maa n waye nigba ti eeyan ko ba tẹlẹ ọrọ awọn dokita lori oogun lilo.